Bukola Awoyemi
Quick Facts
Biography
Bùkọ́lá Àwoyẹmí tí gbogbo ènìyàn mọ̀ sí Arugbá, tí wọ́n bí lọ́dún 1988 jẹ́ gbajúmọ̀ òṣèrébìnrin ọmọ bíbí ìpínlẹ̀ Kwara lórílẹ̀-èdè Nàìjíríà. Òun ni ìyàwó gbajúmọ̀ òṣèré mìíràn tí ó ń jẹ́ Dàmọ́lá Ọlátúnjí.Ó gba orúkọ ìnagijẹ rẹ̀, Arugbá látàrí ipa tí ó kó nínú sinimá àgbéléwò kan tí ògbóǹtarìgì òní-sinimá, Túndé Kèlání gbé jáde lọ́dún 2008.
Ìgbà èwe àti aáyan ìkẹ́kọ̀ọ́ rẹ̀
Wọ́n bí Bùkọ́lá Arugbá ní ìpínlẹ̀ Kwara lọ́dún 1988. Láti ìgbà èwe ni Bùkọ́lá tí fẹ́ràn láti di eléré tíátà. Ó kàwé gbàwé ẹ̀rí nínú ìmọ̀ iṣẹ́ Tíátà ní ifáfitì ìjọba àpapọ̀ ní Ìlọrin, University of Ilorin. Nígbà tí ó ń kẹ́kọ̀ọ́ ló ti ń gbìyànjú láti máa ṣeré tíátà, ṣùgbọ́n ìràwọ̀ rẹ̀ kò tàn àfi ìgbà tí ó kópa nínú sinimá àgbéléwò tí Túndé Kèlání dárí lọ́dún 2008,tí àkọ́lé rẹ̀ ń jẹ́ Arugbá. Lẹ́yìn náà o tún kópa nínú "Poisonous Affair" àti àwọn sinimá-àgbéléwò gbankọgbì mìíràn lédè Yorùbá. "Ìgbà Ǹ Bá Jó" ni sinimá àgbéléwò àkọ́kọ́ tí Bùkọ́lá Àwoyẹmí ṣe agbátẹrù rẹ̀ fún ara rẹ̀ lọ́dún 2013.
Àtòjọ díè nínú àwọn sinimá-àgbéléwò rẹ̀
- Arugbá
- Poisonous Affair
- Church on Fire
- Akpochereogu
- Ire Okùnkùn
- Ìgbà Ǹ Bá Jó