Mercy Macjoe
Quick Facts
Biography
Mercy Ima Macjoe, tí ó gbajúmọ̀ gẹ́gẹ́ bí Mercy Macjoe tí wọ́n bí lógúnjọ́ oṣù kẹfà ọdún 1993 (June 20 1993) jẹ́ gbajúmọ̀ Òṣèrébìnrin, olóòtú sinimá àgbéléwò àti oníṣòwò ọmọ Nàìjíríà. Ó di gbajúmọ̀ ìlúmọ̀ọ́ká fún ipa tó kó nínú sinimá Jenna' 'àti Magdalene. Lọ́dún 2018, wọ́n yàn án láti díje fún àmìn-ẹ̀yẹ fún amúgbálẹ́gbẹ̀ẹ́ olú-ẹ̀dá-ìtàn tó dára jù lọ ti City People Awards bẹ́ẹ̀ ló gbàmìn ẹ̀yẹ tí Hollywood and African Prestigious Awardsfún Òṣèré fún lọ́dún 2019.
Iṣẹ́ rẹ̀
Gégé bí onísinimá àgbéléwò
Mercy bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ sinimá àgbéléwò lọ́dún 2011 pẹ̀lú ipa tó kó nínú sinimá Lonely Princess pẹ̀lú gbajúmọ̀ Òṣèrébìnrin Mercy Johnson.Lẹ́yìn ìgbà náà ló ti ń kópa nínú oríṣiríṣi sinimá, tí ó sìn di ìlúmọ̀ọ́ká. Lára àwọn sinimá tí ó ti kopa ni; Midnight Crew, Zenith of Love, Shame, Bread of Life, Girl Next Door àti Flaws. Ní ìbẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ sinimá rẹ̀, ó ti báwọn kópa nínú àwọn sinimá àgbéléwò tí orílẹ̀-èdè Ghana. Lọ́dún 2018, ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ènìyàn ló wa ẹnu sí i, tí ọ̀pọ̀ sìn gbóríyìn fún un nípa ipa tó kó nínú Sinimá Jenna. Lọ́dún 2020, bẹ̀rẹ̀ ẹ̀kọ́ ní ilé ẹ̀kọ́ sinimá ti New York Film Academy.
Gẹ́gẹ́ bí olóòtú sinimá àgbéléwò
Lọ́dún 2018, ó ṣe olóòtú Sinimá àgbéléwò rẹ̀ àkọ́kọ́ tí ó pè ní Red, tí wọ́n sìn ṣe àfihàn rẹ̀ ní Ìbákà TV, pẹ̀lú àwọn gbajúmọ̀ àwọn Òṣèré bíi Nonso Diobi, Ifeanyi Kalu àti Mercy Macjoe, tí ó kópa olú-ẹ̀dá-ìtàn fún ara rẹ̀in. Lọ́dún 2019, ó tún gbé àwọn sinimá gbankọgbì mẹ́ta jáde ti àkọlé wọ́n ń jẹ́, 30 and Single, ó yà èyí ní London, Love in a Puff àti Passion’s Promise.
Awards and Recognition
Ọdún | Ètò | Àmìn-ẹ̀yẹ | Olúborí | Èsì |
---|---|---|---|---|
Ọdún 2016 | Scream Awards | Ìràwọ̀ tuntun Òṣèrébìnrin lágbo Sinimá àgbéléwò tó tayọ jù lọ | Mercy Macjoe | Gbàá |
Ọdún 2017 | City People Movie Awards | Òṣèrébìnrin tó dára jù lọ | Mercy Macjoe | Wọ́n pèé |
2018 | City People Movie Awards | Amúgbálẹ́gbẹ̀ẹ́ olú-ẹ̀dá-ìtàn obìnrin tó dára jù lọ Best Supporting | Mercy Macjoe | Wọ́n pèé |
CA Award, London | Òṣèrébìnrin tó dára jù lọ | Mercy Macjoe | Gbàá | |
2019 | Humanitarian Award | Oníṣòwò gbajúmọ̀ Òṣèrébìnrin tí ọdún náà | Mercy Macjoe | Gbàá |
GMYT African Humanitarian Award | Òṣèrébìnrin tí fáàrí rẹ̀ dára jù lọ́dún náà | Mercy Macjoe | Gbàá | |
Hollywood and African Prestigious Awards, Los Angeles | Sinimá àgbéléwò tó dá dúró jùlọ ní Áfíríkà | Love in a Puff | Gbàá |
Àtẹ àwọn sinimá àgbéléwò rẹ̀
Àtẹ àṣàyàn àwọn sinimá àgbéléwò rẹ̀
- Jenna
- Midnight Crew
- Zenith of Love
- Shame
- Bread of Life
- Girl Next Door
- Flaws
- Magdalene
- Red
- Obsessed alongside Daniel K Daniel
- Wedding Eve
- Forbidden Pleasure
- Somewhere in Hell
- Body of a Virgin
- Moonwalker
- Bonded by Fate