Kemi Afolabi
Quick Facts
Biography
Kẹ́mi Afọlábí (tí wọ́n bí ní ọjọ́ kẹrìndínlọ́gbọ̀n oṣù kẹrin ọdún 1978) jẹ́ gbajúmọ̀ òṣèrébìnrin, oǹkọ̀tàn àti olóòtú sinimá àgbéléwò ọmọ ìpínlẹ̀ Ògùn, ṣùgbọ́n tí àwọn òbí rẹ̀ bí sí ìpínlẹ̀ Èkó lórílẹ̀ èdè Nàìjíríà.
Ìgbà èwe àti aáyan ìkẹ́kọ̀ọ́
Kẹ́mi bẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ rẹ̀ ní ilé-ìwé A-Z International School àti ilé-ìwé Our Lady of Apostles School, ní ìpínlẹ̀ Èkó lórílẹ̀ èdè Nàìjíríà fún ẹ̀kọ́ gírámà rẹ̀. Lẹ́yìn èyí, ó kàwé gboyè nípa ìmọ̀ òfin ni ifáfitì ìjọba àpapọ̀ ti ó kalẹ̀ sí ìlú Èkó, the University of Lagos. Lẹ́yìn tó dára pọ̀ mọ́ ìṣe sinimá àgbéléwò, Kẹ́mi tí gba àmìn ẹ̀yẹ tí ilé iṣẹ́ City People ṣe gẹ́gẹ́ bí òṣèrébìnrin tó dára jùlọ lọ́dún 2016, lọ́dún kan náà, ó gba àmìn ẹ̀yẹ gẹ́gẹ́ bí òṣèrébìnrin to gbajúmọ̀ jùlọ láti owó Odua Image Awards. Kẹ́mi Afolábí jẹ́ abilékọ, ó sìn tí bímọ kan péré.