Alade Aromire
Quick Facts
Biography
Muyideen Agboọlá Àlàdé Arómirẹ́ tí gbogbo ènìyàn tún mọ̀ sí Àlàdé Arómirẹ́ tí wọ́n bí ní Ìpínlẹ̀ Èkó ní ọjọ́ Kẹtàlá oṣù Kẹjọ ọdún 1963 jẹ́ gbajú-gbajà òṣèré ìtàgé, agbéré-jáde, àti ònkọ̀tàn ọmọ orílẹ̀-èdè Nàìjíríà.
Ètò-ẹ̀kọ́ rẹ̀
Àlàdé lọ sí ilé-ẹ̀kọ́ alákọ̀ọ́bẹ̀rẹ̀ ti Ansar-ud-Deen tí ó wà ní Alakoso ní Ìpínlẹ̀ Èkó, tí ó sì lọ sí ilé-ẹ̀kọ́ girama ti Ansar-ud-Deen College, ní Ìlú Ìsọlọ̀ ní Ìpínlẹ̀ Èkó kan náà. Ó tún kọ́ ẹ̀kọ́ nípa eré oníṣẹ́ níSchool of Arts rí ó wà ní Apapa.
Iṣẹ́ rẹ̀
Gẹ́gẹ́ bí òṣèré, ó ti rí gbogbo rògbàdìyàn àti akitiyan tí ó wà nínú lílo ìlànà "atabloid" tí àwọn àgbà òṣèré bíi: Moses Ọláìyá Adéjùmọ̀, Olóyè Hubert Ògúndé ń lò láti gbé eré jáde tí ó sì ń ná wọn lówó gegere kí eré náà ó tó jáde síta fún àwọn ènìyàn. Ó dá ṣíṣe yíya eré sinimá àgbéléwò àkókọ́ sílẹ̀ tí ó pe àkọọ́lé rẹ̀ ní Ẹkùn ní ọdún 1989.