Murphy Afolabi
Nigerian actor
Intro | Nigerian actor | |
Places | Nigeria | |
was | Actor | |
Work field | Film, TV, Stage & Radio | |
Gender |
| |
Birth | 5 May 1974 | |
Death | 14 May 2023 (aged 49 years) | |
Star sign | Taurus |
Murphy Afolabi tí wọ́n bí ní Ọjọ́ karùn-ún oṣù karùn-ún ọdún 1974 (5th May, 1974) jẹ́ gbajúmọ̀ òṣèré, olùdarí àti oǹkọ̀tàn sinimá àgbéléwò ọmọ orílẹ̀ èdè Nàìjíríà.
Murphy Afọlábí dii olóògbé níí Ọjó kẹ́rínlà oṣù karùn-ún ọdún 2023 (14th May, 2023).
Wọ́n bí Afọlábí ni ìpínlẹ̀ Ọ̀ṣun lórílẹ̀ èdè Nàìjíríà. Ó kàwé gbàwé ẹ̀rí nínú ìmọ̀ ìbánisọ̀rọ̀, tíátà àti ètò nípa ṣíṣe sinimá ni ile ìwé Ìré Polytechnic. Ó bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ tíátà lábẹ́ àgbà òṣèré sinimá àgbéléwò tí a mọ̀ sí Dágúnró, nígbà tí ó kópa nínú sinimá àgbéléwò kan tí àkọ́lé rẹ̀ ń jẹ́ Ifá Olókun. Lẹ́yìn èyí ó ti kópa nínú sinimá àgbéléwò tí ó ti ju ọgọ́ta lọ.