Lizzy Àńjọọ́rìn tí orúkọ rẹ̀ gangan ń jẹ́ Elizabeth Ìbùkúnolúwa Àńjọọ́rìn (tí wọ́n bí ní Ọjọ́ kẹrin oṣù kẹrin) jẹ́ gbajúmọ̀ òṣèrébìnrin, olùdarí àti olóòtú sinimá àgbéléwò ọmọ bíbí ìjọba ìbílẹ̀ Àgbádárìgì ni ìpínlẹ̀ Èkó lórílẹ̀ èdè Nàìjíríà. Lizzy jẹ́ oníṣòwò bákan náà.
Aáyan rẹ̀ nínú iṣẹ́ tíátà
Lẹ́yìn tí ó di òṣèré sinimá àgbéléwò, ó ti ṣe olóòtú sinimá àgbéléwò mẹ́fà fúnra rẹ̀. Àwọn sinimá-àgbéléwò náà ni
- Tolani Gbarada;
- Gold;
- Iyawo Abuke;
- Kofo Tinubu;
- Kofo De First Lady;
- Owo Naira Bet.
Bákan náà, ó ti kópa nínú sinimá àgbéléwò kan bii;
- Owowunmi (2010);
- Arewa Ejo (2009);
- Ise Onise (2009).
Àwọn Ìtọ́kasí