Biography
Also Viewed
The basics
Quick Facts
The details
Biography
A bí Délé Òdúlé tí a bí lọjọ́ kẹtàdínlógún, oṣù kọkànlá ọdún 1961 jẹ́ àgbà òṣèré tíátà àti olótùú-àgbà. Ní ọdún 2014, wọ́n yaǹ-án láti gba àmìn-ẹ̀yẹ gẹ́gẹ́ bí amúgbálẹ́gbẹ̀ẹ́ òṣèré Yorùbá ni (Best of Nollywood Awards) fún ipa tí ó kó nínú sinimá àgbéléwò "Kori Koto". Òun ààrẹ àwọn òṣèré tíátà àti sinimí àgbéléwò ní orílẹ̀-èdè Nàìjíríà
Ìgbéayé Délé Òdúlé Ni Ìbẹ̀rẹ̀pẹ̀pẹ̀ Àti Bí Ó Ti Kẹ́kọ̀ọ́
A bí Délé Òdúlé ní ìlú Òrù-Ìjèbù, Ní Ìjọba Ìbílè Ijebu North ti ìpínlẹ Ogun ní ọdún 1961. Ibè ni ó ti ka ìwé àkọ́bẹ̀rẹ̀ àti gíga. Ó kẹ́kọ̀ọ́ gboyè Olùkọ̀ onípele kejì (Teachers' Grade II Certificate) ní Oru kí ó tó tẹ̀síwájụ́ ẹ̀kọ́ ní University of Ibadan, ní ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ níbi tí ó ti ń kọ́ nípa ìmọ̀ tíátà (Theatre Arts.)
Àdàkọ:Inc-filmInc-film
Awọn atokọ ti eré re
- Ti Oluwa Ni Ile (1993)
- Lakunle Alagbe (1997)
- Oduduwa (2000)
- Afonja (2002)
- Olorire (2003)
- Ògédé Didùn (2003)
- Ogbologbo (2003)
- Suku Suku Bam Bam (2004)
- Omo Olè (2004)
- Iwe Akosile (2005)
- Idajo Mi Tide (2005)
- Eru Ife (2005)
- Ó kojá Ofin (2007)
- Aye Ibironke (2007)
- Bolode O'ku (2009)
- Aworo (2012)